Take a fresh look at your lifestyle.

Ólé Ní Ẹgbẹrin Àwọn Ènìyàn Ni ilu Ibadan Tí Wọ́n Jẹ Anfààní Iṣẹ Abẹ Ọ̀fẹ́.

121

Ólé ní Ẹgbẹrin Àwọn Ènìyàn ni ìlú Ìbàdàn tí wọn ní jẹ anfààní ìwòsàn ọ̀fẹ́ nípa iṣẹ́ Abẹ láti ọ̀dọ ilé iṣé alaadani tí ẹsìn isalam ti wọn ń pé ni ATF.

Wọ́n ní Ètò iṣẹ́ Abẹ Ọ̀fẹ́ yìí yóò kakiri agbègbè ìlú Oyo fún Àlàáfíà àwọn ènìyàn.

Àwọn iṣé Abẹ Ọ̀fẹ́ yìí wà fún àwọn tó bá ni àìsàn jẹjẹrẹ, ipenija ojú, ipenija eyín àti bẹbẹ lọ.

Dókítà Ridwan Salam to jẹ alákòóso fún ẹgbẹ́ náà ni ìlú Oyo ló sọ di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn níbi ìparí ètò ọlọ́jọ́ mẹta náà.

Ó ní ìpinu àwọn ní láti ran àwọn ènìyàn lówó àti àwọn ti kò ní owó láti ṣe ìtọ́jú ará wọn.

Salam tun fi yẹ àwọn ènìyàn wí pé ẹlẹ́kesàn irú rẹ́ rẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò má ṣe Ìrànlọ́wọ́ ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún àwọn ènìyàn láàrin ọdún mẹta.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn tó n jẹ anfààní náà kí n ṣe àwọn ará Òyó nikan àwọn ará Kwara, Eko,ogún ati Osun o gbẹ́yín

Ó wá fi àsìkò náà dupe púpò lówó àwon ènìyàn tó ń ṣe alátìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ náà, bákanáà ó rọ àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti dá sí ètò náà àti láti ṣe Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó kún diẹ fún.

Àwọn tó jẹ anfààní ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ náà, Iyaafin Adéọlá Oguntoye to wọn ṣiṣẹ Abẹ fún ọmọ rẹ ọdún méjì àti ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ náà àti adura wí pé Ọlọrun yóò túnbọ̀ rán wọn lọ̀wọ̀.

Comments are closed.

button