Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìlú Eko Ṣetán Láti Ṣe Ìrànlọ́wọ́ Ètò Ìwòsàn Ọ̀fẹ́ Fún Ẹgbẹ̀rún Márùn-ún Àwọn Ènìyàn Ni Ìpínlẹ̀ Eko.

117

Awọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọn gbé ni òkè òkun, ti orúkọ ẹgbẹ náà jẹ Ọmọ Ìlú Eko, ní àwọn ti ṣetán láti ran àwọn ènìyàn ẹgbẹrun marun-un lọwọ fún ìwòsàn ọfẹ kakakiri agbègbè ìlú Eko.

Nígbà tí wọn ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ Ìwòsàn ní Ipaja ni ilu Eko, wọn ní ìpinu yìí wà fún àwọn ènìyàn tó kún diẹ fún àti láti ṣe atilẹyin fún àwọn ilé ìwòsan ìjọba, pàápàjúlo fún àwọn aláboyún.

Wọn ní àwọn ni ìgbàgbó wí pé ètò ìwòsàn ọfẹ yìí yóò kó ipa tó ní ìtumọ láàrin àwọn ènìyàn ìlú Eko.

Wọn tẹsiwaju wí pé àwọn agbègbè márùn-ún ni yóò je anfààní ètò náà, agbègbè Ikorodu,Epe, Badagry, Ikeja, ati Lagos Island.

Iyaafin Lola Ogbara Alogba tó jẹ́ alága níbi ayẹyẹ naa ni ọdọdún ni ètò náà wà ń wáyé fún ìdàgbàsókè ìlú Eko àti àwọn agbègbè rè.

Ọkan lára àwọn tó jẹ anfààní ètò náà Ọgbẹni Emmanuel Ayeni dupẹ lọwọ Ẹgbẹ́ omo ìlú Eko fún anfààní náà

Pínpín ogún ọ̀fẹ́ kò gbẹ́yín níbi ayẹyẹ náà.

Comments are closed.

button