Take a fresh look at your lifestyle.

Ọmọ-Bíbí Nàìjíríà, Kemi Badenoch Dí Olórí Ẹgbẹ́ Òṣèlú ‘Conservative’ Tí Biritiko

Lekan Orenuga

281

Ọmọ bíbí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Kemi Adegoke Badenoch ni wọ́n tí dìbo yàn gẹ́gẹ́ bíi olórí túntún fún ẹgbẹ́ òṣèlú ‘Conservative’ tí Orílẹ̀-èdè Biritiko.

‎ Kemi, tó dàgbà sí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ìbí rẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì, dí Obìnrin àkọkọ́ nílẹ̀ Áfíríkà láti ṣé olórí ẹgbẹ́ òṣèlú nlá náà nílùú Gẹ̀ẹ́sì.


‎ Badenoch, ọmọ ọdún mẹ́rin-lé-logóji (44), rọ́pò Alákòóso ìjọba (Prime Minister) tẹ́lẹ̀ rí, Rishi Sunak lẹyìn tó ṣẹgun ìdìbò adari pẹ̀lú ìpinnu láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú náà pàdà sípò asíwájú rẹ àti ìyípadà sí réré lẹyìn tí wọ́n tí fìdí rẹmi níbi ìdìbò gbogbogbò tó wáyé ní Oṣù Keje, ọdún yìí.

‎ Lẹ́yìn ìdìbò adari gígùn oloṣu kán, o ní ibo ìdá mẹta-din-lọgọta nínú ọgọ́ọ̀rún (57%) láti ọdọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́, nígbàtí Mínísítà wíwọlé àti ijádé tẹ́lẹ̀ rí Robert Jenrick, ní ibo metalelogoji (43%).

‎ Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jakejado àgbáyé náà fí ìdùnnú wọ́n hàn lórí Kemi Badenoch. Àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn pàtàkì ní Nàìjíríà náà tún tán imọlẹ̀ sí àwọn ìdàgbàsókè tí yóò wáyé nínú ìdìbò Ẹgbẹ́ ‘Conservative’.

‎ Alákòóso ìjọba Orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì tẹ́lẹ̀ Boris Johnson gbóríyìn fún ìgboyà àti ṣíṣe mímọ Badenoch, èyí tí yóò mú òun gbogbo lọ́ bó tí tí nínú ẹgbẹ́ náà.

‎ Oríṣiríṣi àṣeyọrí ní àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ṣé ní Orílè-èdè Gẹ̀ẹ́sì èyí tó tí fí àwọn kan hàn bíi Anthony Joshua, (afẹṣẹja), òṣèré John Boyega, Pearlena Igbokwe, Chibundu Onuzo, oni gege-ara láàrin àwọn mìíràn.

Comments are closed.

button