Ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Oluremi Tinubu tí ké sí àwọn obìnrin Nàìjíríà láti ṣé akójọpọ̀, àtìlẹ́yìn, ìgbìyànjú àti ṣiṣẹ́ takuntakun fún èyí k’eyi Obìnrin tó bá n wá ọnà láti bọ́ sípò.
Arábìnrin yìí ń s’ọrọ níbí Ìpàdé àti Ifọrọwanilẹnuwo tí àwọn Obìnrin tí ẹgbẹ́ òṣèlú ‘All Progressives Congress (APC)’ nílùú Abuja, èyítí o ní àkòrí ‘Iró Àwọn Obìnrin Ẹ̀gbẹ́ Òṣèlú APC Lágbára àti Ìtẹ̀síwájú Orílẹ̀-èdè.’
Àwọn tó wà níbí ìpàdé náà ní Ìyàwó Igbákejì Ààrẹ, Nana Shettima, Ayá Ààrẹ tí Gambia, àwọn Obìnrin ọmọ Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin tí Orílẹ-èdè, Àwọn Obìnrin àkọkọ tí ìpínlẹ̀, àwọn Obìnrin igbákejì Gómìnà, àwọn Olùdarí Obìnrin tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti gbogbo orílẹ-èdè Nàìjíríà, àti káàkiri àgbáyé.
Ìyáàfín Tinubu ṣé àlàyé pẹ̀lú áwọn àpẹẹrẹ pé ẹní tó tó lè lóyè Obìnrin ní Obìnrin mìíràn.