Andrea Iannone yóò kópa níbi Idije Alùpùpù àfisáré Malaysian Grand Prix, pẹ̀lú ikọ̀ – Valentino Rossi-owned VR46 Racing lẹ́yìn Ìdúró Ọdún Mẹ́rin ti o ti wà lórí òté.
Ní osù kọkànlá, ọdún 2019 ni Ọ̀gbẹ́ni Iannone ti lugbadi ọ̀ràn steroid Drostanolon tí wọ́n sì ti fòfin dé lẹ́yìn àyẹ̀wò ìtọ̀ rẹ̀.
Àwọn aláṣẹ Eré ìdárayá – FIM ti kókó fún ni oṣù mejidinlogun láti lọ rọ́kú nílé ti wọ́n wá pàpà sun sí ọdún mẹrin ni igbeyin láti ọdọ àjọ Court of Arbitration for Sport (CAS) ti àjọ World Anti-Doping Agency (WADA) bẹ̀bẹ̀ fún.
Ọ̀gbẹ́ni Lannone sọ pé gbogbo eléyìí ṣẹlẹ sí ohùn latari ẹran tó lábàwọ́n ti òun jẹ. Ọmọ ọdún màrúndínlọ́gbọ̀n náà tiwá ní ànfànií báyìí láti kópa nínú ìdíje
Superbike World Championship ti ọdún yíìí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san