Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Nipa Iṣẹ́ Ọnà Ṣèlérí Àjọṣepọ̀ Pẹ̀lú Mínísítà Àná, Ade-John Fún Ìgbéga Ètò Ìrìnàjò Àti Ìgbafẹ́

154

 

Mínísítà iṣẹ́ ọnà, àṣà àti ìrìnrìnàjò àti ọgbọ́n àtinúdá ọ̀rọ̀ aje, Hannatu Musawa ti sọ pé òún yóò gba ìmòràn ati iriri ẹni iṣaju òun, Lola Ade-John lò fún ìtèsíwájú ẹ̀ka náà.

Níbi ayẹyẹ ìfisẹ́léniilọ́wọ́ ni Ọ́fíìsì rẹ̀ ni Abuja, Mínísítà gbórìyìn fún Iyaafin Ade-John fún àṣeyọrí rẹ̀ ni àsìkò tó lò ní Ọ́fíìsì.

Ìyáàfin Ade-John wá gbósùbà fún ààrẹ
Bola Ahmed Tinubu fún òòrè ọfẹ láti sìn ninu ètò ìjọ̀ba rẹ̀. Ó wá pinnu atilẹyin fun Mínísítà Musawa.

Akọ̀wé Àgbà, Ìyáàfin Patricia Ibiene Roberts, OON wà níbí ayẹyẹ náà pèlú àwọn lọ̀gálọ̀gá ti àjọ Tourism Development Authority NTDA àti National Institute for Hospitality and Tourism, abbl.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button