Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú BDP Tó Ń Se Ìjọba Lọ́wọ́ Fìdí Rẹmi Nínú Ètò Ìdìbò Ni Orílẹ̀-èdè Botswana

143

 

Ẹgbẹ́ Òṣèlú Botswana Democratic Party (BDP) ti fìdí rẹmi ninu idibo ọ̀pọ̀ ile asofin ti ọsẹ yíì bi iroyin aladani iwe ìròyìn Mmegi se sọ ati ti ẹ̀rọ asọ̀rọ̀má- gbèsì ti ipinlẹ to gbe èsì ìbò lati bíi ìlàjì Konsituensi jade.

Ààrẹ Mokgweetsi Masis ti ẹgbẹ́ òsèlú BDP, ló ti n dari ilẹ̀ náà lati ẹyin ìgbà òmìnira lọwọ àwọn ìjọba Gẹẹsi .
Ẹgbẹ́ òṣèlú BDP ṣẹṣẹ bori ẹyọkan soso ninu Kọ̀nsítúẹ́nsì mẹ́rìndínlógójiì, Ẹgbẹ alatako, Umbrella for Democratic Change (UDC) si ti ni mẹ́tàlélógún.

Ní ọ̀nà lati ni ibujoko to pọ̀ nínú òsèlú wọn, Ẹgbẹ ni lati ni ibujoko mọ́kànlelọ́gbọ̀n.

Orilẹ̀-ède Botswana ni wọn mọ̀ sí iduro -sinsin ni gbogbo ẹka, wọn ni ọrọ òhún isembaye alumọni diamondi, wọn pèsè ìlera ọfẹ ati ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún mílíọ̀nù meji o le díẹ̀ àwọn ọmọ orilẹ̀-èdè rẹ, Ó tún wà lára àwọn orilẹ-ede to n pèsè diamondi jù lágbáyé.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button