Aya Ààrẹ orílẹ̀-èdè yíì, Oluremi Tinubu ti iyawo igbakeji ààrẹ, Nana Shettima sojú fún ti pín àwọn ounjẹ fún àwọn Mẹ̀kúnù ni ìpínlẹ̀ Èkìtì.
O sọ wipe eto ìrètí ọtun – Renewed Hope Initiative (RHI) ti ààrẹ Bola Tinubu, jẹ ti olósoosù fun àwọn ti ko rí jájẹ ni awujọ láti tun ran ijobya lọwọ lati gbọ́ diẹ lara bùkátà àwon èniyàn.
O fi kun pé kí àwon to jẹ anfaani eto náà máṣe lọ ta ni ọjà sugbon ki wọn jẹ igbadun rẹ fún ìgbé ayé ọtun wọn
Iyawo Gómìnà ipinle Ekiti, Dokita Olayemi Oyebanji wa dupe lọ́wọ́ iyawo ààrẹ fún ìnanwọ́ sí wọn ati niti eto ọgbin ni àpapọ̀
” Àwọn àgbẹ obìnrin wa ti rí nǹkan èèlò oko gbà lọwọ ijoba, omiran ni wón si ró lagbara àti àwọn míràn ri Skọ́láshìpù gba,” O sọ èyí.
Eto RHI ni wọn kọ́kọ́ se agbekale rẹ ni Abuja ni oṣù Kejìlá ọdún 2023 tó sì ti tan ka ọpọlọpọ ìpínlẹ̀ lati tu aye àwọn ènìyàn se pàápàá àwọn akanda ẹ̀dá, Obìnrín àti àwọn ọ̀dọ́.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san