Àjọ National Economic Council ti jẹ ko di mímọ pe Àpò Ìfowópamọ́ Owó Epo Àìfọ̀ Nàìjíríà ti wà ni oye to súnmọ́ Ẹ̀ẹ́dẹ̀gbeta Dọ́là – $473,734,57 titi di ọjọ Kọkànlélọ́gbọ̀n osù Kẹwàá, ọdún 2024.
Alága ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà ni orilẹ-ede yíì to tun jẹ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq lo sọ èyí di mímọ ni ọjọ́ Ọjọ́bọ̀.
Gómìnà Abdulrazaq fi kun pé, Àpò Ìfowópamọ́ ti Natural Resources jẹ́ – N26,105,837, 627,67k, ti Àpò Ìfowópamọ́ ti Stabilization náà si jẹ́ – N36,299,482, 763.32k.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san