Àjọ CAF to n dá sẹ̀ríyà fún àwọn tó sẹ̀ – Disciplinary Board of Confederation of African Football (CAF) ti fún fún Nàìjíríà ni Ami Mẹta, Ayò Mẹta fún ìdíje ti wọn kò gbà to yẹ kó wáyé ni ọjọ Kẹẹ̀dógún osù Kẹwàá ọdún 2025 pẹlú orilẹ̀-ède Libya látàrí ìwà ti wọn wù ni ilu Benina orilẹ̀-ède Libya.
Pẹ̀lú ìdájọ́ yíì, ìkọ Eagles ti ni Ami Mẹ́wàá ninu idije merin wọn ṣì lékè tabili, ìkọ Benin ni Ami Meta wọn ṣì wa ni ipo keji, ikọ̀ Rwanda ni Ami marun un ni ipo keta, Libya lọ wà ni ìsàlẹ̀ patapata pẹlú àmi kan soso, wọn ṣì ti já ninu ìdíje náà.
Àṣeyọrí tàbí ọ̀mìn Nàìjíríà pẹlú ikọ̀ Cheetahs ti Benin Republic ni ilu Abidjan
ni ọjọ Ọjọ́bọ̀ ọjọ kẹrinla osù kọkànlá ọdún yi( Ayò ẹlẹ́kàrun ún) yóò mú ki ikọ̀ Super Eagles ni anfààní lati kópa nínu ìdíje ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti yoo wáyé ni
Morocco ni oṣù Kejìlá ọdún 2025 sí osù kínní ọdún 2026.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san