Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Èkó Se Ìfilọ́lẹ̀ – Cultural Mission Movement

158

 

Olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó lori ọ̀rọ̀ nipa arìnrìnajò,iṣẹ ọnà ati ,aṣa, ògbéni Idris Aregbe ti tẹnumọ ojúṣe ijoba ipinle Eko lati gbe asa ipinle naa laruge.

Ọgbẹni Aregbe so eyi nibi Ifilọ́lẹ àjọ Lagos Cultural Mission Movement ni Nike Arts Gallery,  Lekki ni ọjọ Ojobo

Àkòrí eto náà dà lori: ” Itẹsiwaju iwulo Àṣà. Eto náà se igbega oniruru bíi ìfiléde iṣẹ ọnà, ere nipa àṣà ati ounjẹ ilẹ̀ àbínibí wa.

Ọgbẹni Aregbe sọ pé eto náà waye lati jẹ ki àwọn ọdọ lee ba àwọn àgbà ni àjosoyépò ki wọn mọ àsà ipinle wọn lati maje kó parun.

O sọ pé, àjọ Lagos Cultural Mission Movement yóò sọ ìtàn ipinle naa fún gbogbo agbayé.

” A ni lati lee sọ ìtàn wa, ki a joko ka kọ́ nípa iwulo wa”.

Ọ̀gá agba àjọ National Institute of Cultural Orientation, Chief Biodun Ajiboye, sọ pé o se pataki lati jẹki awọn aṣaju wa ọla mọ̀ nipa àṣà orilẹ-ede yíì lati maje ki àṣà to lẹ́wà náà parun.

Alejo pàtàkì ibí ayeye náà, Oluwo ti ilu Iwo ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun,  Oba Abdulrasheed Akanbi wa gbosuba rabandẹ̀ fún ijoba ipinle Eko nipa gbigbe ẹka ọ̀rọ̀ idanilaraya ati aṣa ile wa fáráyé ri.
” Èkó n se bẹbẹ níbi ka gbé àṣà larugẹ,”. ó sọ eyi.

Wọn gbosuba fún oludari Nike Arts Gallery, Iyaafin Nike Okundaye-Davies to wa níbi ayẹyẹ náà fun akitiyan rẹ nipa gbigbe asa laruge.

Okundaye-Davies nitirẹ̀ rawọ ẹ̀bẹ̀ sí Mínísítà abẹ́lé fún ọ̀nà lati jẹ ki iwe igbelu fún àwọn arinajo lee tete ma tẹ̀wọ́n lọ́wọ́.

”A fẹ ki Mínísítà jẹ ki iwe igbelu rọrun fún àwọn tó fẹ́ wa dókòwò. O ṣòro látí ri iwe igbelu Nàìjíríà (Nigerian visa) gbà, a nílàti mójútó èyí.”

 

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button