Ọ̀ọ́dúnrún (300) Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ni Ó Ti Ní Àrùn Jẹjẹrẹ- Àyẹ́wò Sàfihàn Ní Ilé Ìwòsàn Yunifásitì Ìpínlẹ̀ Èkó
Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, ní ilé ìwòsàn Yunifásitì, ìpínlẹ̀ Èkó, Dókítà Abidemi Omonisi ti sàlàyé pé ọ̀ọ́dúnrún àwọn ògo wẹẹrẹ ni àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrun jẹjẹrẹ láàrin odún kan
Omonisi sọ ọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ ìsẹ́gun ní ìlú Abuja nibi eto kan ti o waye lati sàgbéyẹ̀wò ìpalára ti arun jẹjẹrẹ n fa lawujọ
Gẹgẹ bi o se sọ, ìtànkálẹ̀ àìsàn jẹjẹrẹ láàrin àwọn ògo wẹẹrẹ jẹ nnkan ti o léwu léyìí tí ó pè fún àmójútó ni wàrà-ǹ-sesà.