Àjọ tí ó ń mójútò ètò ìlera ìdíle (SFH) pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àjọ elétò ìlera ìpínlẹ̀ Eko ti gbáradì láti gbógunti àìsàn Ìba ní Ìpínlẹ̀ Èkó
Àjọ SFH ń siṣẹ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Banki àgbáyé láti mú àdíkù bá àìsàn ibà pẹ̀lú síṣe ìtọ́jú, pípèsè ògùn sí àwọn ilé ìwòsàn gbogbo ní ìpínlẹ̀ Eko. Fífi ọwọ́ sí ìwé àdéhùn láti siṣẹ́ náà wáyé ní Ọjọ́ Ajé
Àtẹ̀jáde tí ó wáyé ní ọjọ́ Ìsẹ́gun fi yéwa pé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lára àwọn Orílẹ̀-èdè tí àìsàn Ibà ń bá á fínra tí ó sí se é se kí ó se ìkọlù sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Ó wá pàrọwà sí àwọn tí ọ̀rọ̀ kan lati lo anfani naa ki aisan iba le è di àfìsẹ́yìn tí egúngún n fi asọ láwùjọ