Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Pàrọwà Sí Àwọn Ọkùnrin Láti Mú Àdíkù Bá Ọtí Mímu Lójúnà Àti Dènà Àrùn Jẹjẹrẹ
Dókítà Chidiebere Ogo ti gba àwọn Ọkùnrin tí ó ti lé ní ogójì ọdún nímọ̀ràn láti jìnà sí àpọ̀jù ọtí mímu lójúnà àti mu àdíkù bá àrùn jẹjẹrẹ
Ogo, tí ó jẹ́ oníwòsàn àgbà ní ilé ìwòsàn ńlá ti Abẹokuta, ìpínlẹ̀ Ogun ni ó fi ìmọ̀ràn náà léde nígbà tí àwọn oníròyìn fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò ní Ọjọ́rú
Ó sàpèjúwe àpọ̀jù ọtí, ìgbé ayé ìdọ̀tí, àpọ̀jù ìbálòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun kan gbógì tí ó n fa arun jẹjẹrẹ ẹpọ̀n fún ọkùnrin
Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà wá pàrọwà sí gbogbo ènìyàn láti sàmójútó ilera arawọn, ìdárayé lóòrè-kóòrè, àti jíjẹ àwọn oúnjẹ asara lóore láti dènà àìsàn