Soludo Pè Fún Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Láti Sàgbékalẹ̀ Ètò Ọrọ̀ Ajé Èyí Tí Yóò Fìdí Múlẹ̀ Sinsin
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Soludo ti ké sí tolórí-tẹlẹ́mù láti fọwọ́sowọ́pọ̀ fún ìsàgbékalẹ̀ ètò ọrọ̀ ajé tí ó múná dóko
Ó pe ìpè náà níbi àpérò kan tí ó wáyé ní ìlú Abuja níbi tí o ti pè fún ríran àwọn ilé iṣẹ́ tiwa-n-tiwa lọ́wọ́ fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé
Gómìnà Soludo sàfirinlẹ̀ pàtàkì fífi Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà síwájú láti se ìgbélárugẹ fún àwọn ilé iṣẹ́ abẹ́lé fún àseyọrí àti ìdàgbàsókè aláìlẹ́gbẹ́