Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara Pẹ̀lú Yunifásitì Al-Hikma Ti Ní Ìfẹnukò Fún Ìdásílẹ́ Ilé Ìwòsàn Àpapọ̀
Lójúnà àti mú ìgbòòrò bá ètò ìlera àti ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara, ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara ti gbé ìgbésẹ̀ akin pẹ̀lú bíbuwọ́lu ìwé àdéhùn kan pẹ̀lú Yunifasiti Al-Hikma èyí tí yóò mú kí ìdásílẹ̀ ilé ìwòsàn gbogbogbòò wáyé ní àgbègbè Sobi, Ìlú Ilọrin
Bíbuwọ́lu ìwé àdéhùn náà wáyé níbi ayẹyẹ kan tí ó wáyé ní gbọ̀ngàn ẹka ètò ìlera ti ìpínlẹ̀ Kwara lati mu ìgbòòrò ba ètò ìlera àti ìdàgbàsókè ètò ẹ̀kọ́
Kọmísọ́nà fún ètò ìlera, Dokita Amina Ahmed El-Imam sapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi eyi ti o dara ti yoo si mu ki ìbásepọ̀ ti o dan manran waye láàrin ìjọba àti ajọ aládàníi