Orílẹ̀-èdè Ukraine ti sẹ́ ẹ̀sùn ti wọn fi kàn pé wón n pèsè Dírònù ija ogun fún ọmọ ogun ọlọtẹ to n dojú kọ ologun ilẹ̀ Mali ati ajagunta ti ilẹ̀ Russia satilẹyin fún.
Orile-èdè Mali pẹlu ojugba wọn, Niger ati Burkina Faso, níbití ologun ti n se ijọba ti fẹsun kan Kyiv tẹlẹ pé o n se atilehin fún àwọn agbegbọ̀n ni agbegbe Sahel lẹ́yìn ti awọn Oṣiṣẹ Ukraine ti sọ tẹlẹ ni ibẹrẹ ọdun yí pé orile-èdè náà n slatilẹyin fun àwọn ọmọ ogun ọlọtẹ.
Ilẹ̀ Russia gbogun ti orile-èdè Ukraine ni ọdún 2022 titi di asiko yii.
Lèyìn ti ọpọlọpọ ilẹ̀ alawọ funfun ko bawọn dasi latari ogun náà, o fẹ wọlé sára ile Adulawọ lati orile-èdè Mali nipasẹ ti oselu ati eto aabo bí wọn se sọ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san