Ọkọ̀ Bọ́ọ̀si to ko ọpọlọpọ akẹ́kọ̀ọ́ Ifáfitì
ni Ariwa ila oorun Egipti ti ni ijamba tó sì pa eniyan méjìlá ti mẹtalelọgbọn sí farapa bi eleto ìlera se sọ.
Àwọn akékòó náà n ti yara ìkàwé wọn bọ pada wa sí ayé wọ́n ki isele to gbomi loju ènìyàn náà to sẹlẹ bi àwọn oníròyìn agbegbe se sọ.
Ọkọ Ámbúlànsì ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsan. Mínísíri ko sọ ohun to fa ijamba náà, wọn ti mú awakọ lati wadi okunfa ijamba náà.
Mínísítà ètò ìlera ati eto ẹkọ ,Khaled Abdel-Ghaffar àti Ayman Ashour ti lọ se àbẹwò si idile àwọn akékọ̀ọ́ ti ijamba náà ṣẹlẹ sí.
Irufẹ iṣẹlẹ náà a ma wáyé ni ilẹ̀ Egipti ni ọdọọdún latari ọna ti ko dara, ere asaju ati agbofinro ọkọ ti ko se iṣẹ wọn daradara botiyẹ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san