Ilé Ìfowópamọ́ Àgbáyé ti ke sí ìjoba àpapọ láti sa ipá wọn, fún ètò Ààbo Tó Péye Fún Àwọn Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Wọ́n ní, àwọn sọ èyí látàrí bí àwọn nkán ṣe di ọ̀wọn gọ́gọ́, tí ó sì ń Ṣe àkóbá fún àwọn ènìyàn pàápàá jùlọ àwọn Ọmọ kékèké.
Ìgbákejì fún Ààrẹ ilé Ìfowópamọ́ Àgbáyé Indemit Gill ló so èyí di Mímọ níbi ayẹyẹ ìpàdé ìdókòwò ti ọdún 2024 to Wáyé ní ìlú Abuja
Ó ní bí, ètò ìdókòwò Orílè-èdè Naijiria ti ń lo yii, wọ́n nílo láti Ṣe àwọn àtúnṣe ní kíákíá tí yóò mú ìdàgbàsókè àti Àlàáfíà bá àwọn ènìyàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó ní láàrin ọdún mẹwàá sí mẹ́dọ̀ọ́gùn àwọn ìjọba apapo ní láti gbé ìgbésẹ fún àtúnṣe ọ̀wọn gógó tó ń ló lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.