Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Chad: Ìkún Omi Sọsẹ́ Fún Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Ènìyàn

134

 

Agbègbè tó lé lógún ní orilẹ-ede Chad ni àrọ̀ọ̀dá Òjò ti sọsẹ́ tó sì ti fa ìkún omi tó lágbára, orilẹ̀-èdè níbití rògbòdìyàn oúnjẹ ti ń ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀ lemọ́lemọ́.

Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ènìyàn ló ti ta téru nípàá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí ló ti di aláìnílélórí látàrí ìkún omi náà.

Ni àfikún, Sarè oko to ju irinwó ẹgbẹ̀rún ló ti bàjẹ́ tó sì ti fa ọ̀wọ́n oúnjẹ ni orílẹ̀-èdè náà níbití ebi ti fẹ́ẹ̀ gbẹ̀mí àwọn ènìyàn tó dín ní Mílíọ̀nù mẹ́rin

Ohun èèlò àti irin isẹ́ ló ti dẹnu kọlẹ̀ níbití àgbàrá Òjò ti gbé ọ̀pọ̀ ọ̀nà àti afárá lọ bámúbámú tó ti wá fa àilewọ̀ àwọn àgbègbè náà láti ọwọ́ àwọn tó fẹ́ se ìrànwọ́

Aláboyún ti bára wọn ní ọgbà ìrànwọ́ ìjọba níbi ti wọn kò ti ni ìtọ́jú tó péye

Ní ọ̀nà lati jẹ́ ki àwọn ìṣòro wọ̀nyí di àfìsẹ́yìn, àwọn Agbẹ̀bí elétò ìlera àádọta dín méjì ó lé Nígba ni wọ́n ti rán lọ sí àwọn ìlú náà, tí wọ́n sì ti pín àwọn ohun èèlò ìlera fún àwọn Obìnrin àti Ọ̀dọbínrin tó jẹ́ Ẹgbẹ̀rún Méjìlá.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button