Olugba àmì ẹyẹ ati irawọ àkòrín ni, Rema.ti ṣetan lati kọrin pẹlu awọn irawọ Olorin bii Cole, SZA ati Nicki Minaj nibi ọdún ayẹyẹ ti Dreamville to n bọ̀.
Ayẹyẹ náà yóò wáyé ni Dorothea Dix Park ni Raleigh, Àríwá Carolina ni Ojo Abameta, ojo kefa, oṣù kẹrin àti ọjọ Aiku, ọjọ keje ti ọpọlọpọ irawọ òṣèré yóò sì ṣere.
Ogbontarigi irawọ akorin ọmọ Naijiria yóò sere ni ọjọ Aiku, yóò kọ ọpọ orin ti awọn ololufẹ rẹ fẹràn lára wọn lati ri : Calm Down’.
Bi ìròyìn se sọ, márùndinlọ́gbọ̀n irawọ àkòrín ni yóò wa síbi ọdún ayeye orin naa.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san