Ogbontarigi akọrin, Kizz Daniel ti ṣetan lati gbe orin ti o pé akọle rẹ ni ‘Twe Twe‘.
Lati ọdún 2015 ti o ti gbe orin ti akọle rẹ je ‘Woju‘, ti awọn ololufẹ re si kójẹ wàràwàrà ni o ti di gbajugbaja akọrin takasufe, Afrobeats ti gbogbo ayé nfẹ lọdọọdun.
Akọrin to gbayi náà n mura láti gbe ‘TZA (Thankz Alot),’ jade. Eleyii ni tiraki márùn ún; Sooner,’ ‘Showa,’ ati ‘Jejeli,’ pẹlu ‘Too Busy To Be Bae’ ati ‘Twe Twe.‘
Nígbà ti o n fi lede lori ẹrọ ayelujara, Kizz Daniel sọ pé orin náà yóò jáde ni ọjọ kọkànlá osu kẹta, ọdún 2024.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san