Mínísítà Fún Àṣà àti Ohun Ìsẹ̀m̀báyé, Hannatu Musawa ti fi àìdùnnú ọkàn hàn látàrí ìkéde ikú gbajúgbajà òsèrè, John Okafor tí gbogbo ayé mọ̀ sí Ọ̀gbẹ́ni Ibu
Adẹ́rìn-ín-pòsónú ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta náà gbé ẹ̀mí mí ní ilé ìwòsàn, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ
Mínísítà sàpèjúwe ikú olóògbé náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó bani lọ́kànjẹ́, èyí tí ó wáyé lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlélógún tí ojúgbà rẹ̀ Sisi Quadri náà jẹ́ Ọlọrun nípè