Ààrẹ Tinubu sèdárò pẹ̀lú ìdílé àwọn gbajú-gbajà òsèré méjì tí ó dágbére f’áyé, John Okafor àti Quadri Oyebamiji. Ó sàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kópa rere láwùjọ látàrí ẹ̀bùn tí olódùmarè fún wọn
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ààrẹ, Ajuri Ngalale fi ọwọ si, Aarẹ Tinubu parọwa si awọn mọ̀lẹ́bí wọn lati ri ìpopàdà naa gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ọlọ́run wi àtipé ipa wọn kò ní parẹ́ láwùjọ títí láyé
Ó gbàdúrà kí Ọlọrun tẹ́wọn si afẹ́fẹ́ rere, ki o si rọ awọn eniyan wọn loju