Oludasile Blue Pictures Cinema, Joy Odiete, ti gba àmì ẹyẹ tó dara ju ti Toronto International Nollywood Film Festival (TINFF) fún isé to tayo ninu Ipese fiimu ilẹ̀ Adulawọ to see mu yangan .
Joy Odiete jẹ gbajúmọ apin fiimu ka nile tabi loke okun, o tilẹ ràn àwọn bíi Warner Brothers Pictures, Walt Disney Pictures, Black Sheep Entertainment àti àwọn studio bee bee lọ ni ile Amerika ati South Africa fún ọdún tó le ni mokandinlogun.
O sise bíi apín-fíìmù-ká, o se oriire pupọ̀ ni studio oke òkun ni ti akọle bíi: Harry Porter, Star Wars, Thor, Avengers, Batman, Iron Man abbl.
O tun ṣiṣe pọ̀ pẹlú àwọn erinllakatabu nidi fiimu agbelewo to milẹ̀ titi bíi : The Return of Jenifa, Phone Swap, Maami, Last Flight to Abuja, The Mirror Boy, ati Anchor Baby abbl.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san