Òṣèré-bìnrin, Laide Bakare ni wọ̀n ti yàn sí ipò – Senior Special Assistant (SSA) sí gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun ni ti ẹka ìdánilárayá àṣà àti ìṣe àti ìrìnàjò.
Bakare fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí òpó ẹ̀rọ ayélujára instagramu rẹ fún oríire náà, o sí ṣèlérí lati sa ipá tirẹ̀.
Ó kọ báyìí, “Èmi náà gẹ́gẹ́ bi Ọ́nárébù, ya Allah, mo dúpẹ́!
Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ náà lọ sí orí òpó ayélujára instagramu rẹ lati kíí kú oríire
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san