Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kóró Ójú Sí Bí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Ṣé Ń Pàdánù Owó-orí Tó Tó Tírílíọ̀nù Mẹ́ta-Dín-Lógún
Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nípasẹ Ìgbìmọ̀ rẹ̀ lórí Ìṣúná ní òwúrọ̀ Ọjọ́ Ajé, bínú sí bí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣé pàdánù Tírílíọ̀nù Mẹ́ta-Dín-Lógún (N17 trillion) láàrin ọdún márùn-ùn lórí amójú kúrò Owó-orí fún àwọn kàn.
Nítorí bẹ́ẹ̀, wọ́n rọ́ Ilé-iṣẹ́ Owó tó ń wọlé ní Orílẹ̀-èdè yíì (Federal Inland Revenue Service FIRS) láti ṣé ìdádúró àwọn irúfẹ́ Owó-orí bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú ètò ìdínkù.
Sẹnetọ Sani Musa (APC Niger East), Alága ìgbìmọ̀ náà tó takò ìpàdánù náà jáde làkókò ìgbéjáde ìṣúná 2024 tí FIRS sí ìgbìmọ̀ rẹ̀ lórí Ìṣúná.
Èyí jẹ́ pàápàá bí Alága tí FIRS, Zacch Adedeji, tí ṣé sọ́ àsọtẹlẹ Tírílíọ̀nù mọkandínlógún lé díẹ̀ (N19.4 trillion) gẹ́gẹ́bí ikojọpọ Owó-orí lápapọ̀ tí wọ́n pinnu fún ọdún 2024, bẹ́ẹ̀ ló tẹnúmọ́ pé Owó-orí túntún tí Tírílíọ̀nù mẹ́ta dín díẹ̀ (N2.7 trilion) tí Ile-iṣẹ́ NNPCL n gbèrò látí fí ṣé Òpópónà ní orílẹ̀-èdè ló yẹ́ kí wọ́n dá dúrò.
Nínú ọrọ̀ rẹ̀, Alága FIRS tún fí tó ìgbìmọ̀ náà létí pé láti gbá àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè yìí sílẹ̀ lọ́wọ́ apọju owó-orí, FIRS, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìgbìmọ̀ kàn tí Ààrẹ Bola Tinubu gbé kalẹ̀, yóò wá ọ̀nà látí dín àwọn owó-orí mejilelogota náà sí mẹ́jọ́.