Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà Tí Rí Àwọn Ọ̀nà Tí Wọ́n Ń Gbà Kó Oúnjẹ Jáde Lórílẹ̀-èdè Náà

204

Ìjọba Nàìjíríà sọ pé àwọn ti ṣàwárí ọ̀nà méjìlélọ́gbọ̀n tí wọ́n fi ń kó oúnjẹ kúrò lórílẹ̀-èdè náà lọ́ àwọn Orílẹ̀-èdè mìíràn.

Ìgbákejì Ààrẹ Kashim Shettima sọ pé ní ọ̀gànjọ́ òru ọjọ́ Aiku, àwọn ọkọ̀ nlá márùnlélógójì (45) tó kó ẹrù àgbàdo ní wọ́n gbá làkókò tí wọ́n nlọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Lẹsẹ kẹsẹ tí wọ́n gbá àwọn oúnjẹ pàdà lọ́ sí ọjà, ìyè owó àgbàdo náà sí walẹ ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá Náírà. O walẹ látí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta (N60,000) sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọta (N50,000), Ìgbákejì Ààrẹ sọ

O sọ èyí ní ọjọ́ Isẹgun làkókò tó n sọrọ ní apejọ kàn tí ‘Public Wealth Management’ ní Abuja, Olú-ìlú orílẹ̀-èdè náà.

Comments are closed.

button