Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ilé-iṣẹ́ Simẹnti Gbá Láti Ṣé Àdínkù Ìyè Owó Simẹnti Sí Ẹgbẹ̀rún Mẹ́jọ́

153

Àwọn Ilé-iṣẹ́ simẹnti tí gbá láti ṣé àdínkù ìdíyelé owó simẹnti látí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (N10,000) sí láàrin ẹgbẹ̀rún méje (N7,000) àtí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ́ (N8,000) fún àádọta Kilogiramu (50kg) tí ìjọba àpapọ̀ bá lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kàn.

Ìpinnu náà wáyé níbí ìpàdé kàn tí Mínísítà fún Àwọn Iṣẹ́ Ìlú, Engineer David Umahi pè.

Umahi tí pé àwọn tí n ṣé simẹnti sí ìpàdé kàn nílùú Abuja lẹ́yin tí owó rẹ̀ tí gá sókè ní àwọn agbègbè sí bíi ẹgbẹ̀rún mẹẹdogun (N15,000) láìpẹ́ yìí ní Orílẹ̀-èdè náà.

Mínísítà fún Ilé-iṣẹ́, Ìṣòwò àti Idoko-owo Doris Uzoka-Anite, wà níbí Ìpàdé náà.

Nígbàtí o nsọ̀rọ lẹyìn ìpàdé náà, Umahi sọ pé àwọn ilé-iṣẹ́ wọnyí ṣàfihàn àwọn ọnà búburú, àwọn owó ọjà àti ìdààmú pàṣípààrọ̀ owó òkèèrè bí díẹ nínú àwọn òkùnfà tó ń fá bí owó simẹnti náà ṣé ń lọ́ sókè.

Comments are closed.

button