Ni ojú òpó ayélujára instagramu gbajúgbajà akọrin ni, Tiwa Savage ti fi lede pe ojú òun n yọ òun lénu lati nnkan bi odun meji si meta bayii.
” Ẹ̀yin ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, láti nǹkan bi odun meji si meta ni mo ti ní ipenija ojú, ti n ba nka kan, n kò ní ríi dáradára “, ó sọ èyí.
Akọrin náà je kó di mímọ̀ bi ìṣòro náà se peleke sí ní igbà to wa ni ilu London.
Bayii ó ti pinnu lati ri Oníṣègùn oyinbo to mọ nipa ìlera ojú kì o lee ba wa nnkan se sí.
Tiwatope Omolara Savage je gbajumo ọmọ Naijiria, to n kọrin, to n kọ orin silẹ, osere-binrin, a tun maa je ọbabìnrin orin
Afrobeats. Savage n ko orin ni ede òyìnbó àti Yoruba; orin re je apopọ̀ orin afrobeats, R&B, afropop, pop ati hip-hop. Ipa ribiribi orin Tiwa Savage sí orin orile-ede Nàìjíríà ti jẹ ki akọrin náà lu àlùyọ, o si ti jẹ́ kó sorí ire.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san