Bi Headies se n padà bò sí orílẹ̀-èdè yìí fún ti ayeye ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlógún, oludari àgbà, ọgbẹni Ayo Animashaun wa pe ipe pé ki ijọba máa ae àtìlẹyìn fún ìfihan àmi ẹyẹ náà.
Bi a kò bà gbagbe ni ọsẹ to kojá, ile iṣẹ
Headies kéde pé àmi ẹyẹ náà n padà bọ̀ wá sí Naijiria leyin ti wọn ti gbe lọ sí ìlu
Atlanta Georgia fún ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀..
Ninu ìfọ̀rọ̀wánilénuwò pẹlu oludari agba
Headies, ọgbẹni Ayo Animashaun sọ pé èròngbà láti gbee wa sí Nàìjíríà je ẹ̀bẹ̀ ti awọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí bẹ̀ láti jẹ kó wá.
O sọ síwájú pé, ni nnkan bi ọdún méjì to kọjá, Headies ti ni àtìlẹyìn to gbúpọn lati ọdọ Ẹ́mbásì ilẹ̀ Amẹ́ríkà to wa ni Nàìjíríà to se àwẹ̀jẹwẹ̀mu fún wọn to tun fun àwọn ọmọ Naijiria ni Visa lati lọ kopa.
Ni nǹkan bi ogun ọdún bayi, ile iṣẹ Headies ti di araba gbajúgbajà to n se àmì ẹyẹ fun orin to ga jùlọ ni Nàìjíríà, eyi si je ki ìlọsíwájú ba orin ni orile-ede yii ati ọdún orin sise.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san