Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ilé Iṣé Nlá Nlá Pe Ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko Láti Dẹ́kun Ìwà ìbàjẹ́ Láti Ọwọ́ Àwọn Oníṣẹ́ Láabi.

0 178

Ẹgbẹ́ àwọn ilé iṣé nla nlá ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti rawọ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko lati Dẹkun ìwà ìbàjẹ́ láti ọwọ́ àwọn láabi.

Wọn ní ìwà ìbàjẹ́ yìí n pa àwọn lára púpọ̀ nítorí o ṣe àkóbá nla fún dukia àti ilé iṣé.

Ọ̀gá Àgbà Pátápátá fún àjọ náà Ṣẹgun Ajayi-Kadir sọ èyí di mímọ̀ níbi ìpàdé ọdọọdún to n ma waye fún ẹgbẹ́ náà ni Ikeja.

Ó ní kò yẹ ki ìdààmú wa láàrin ìjọba àti àwọn ilé iṣé nlá nlá kó tó di wí pé ètò ọ̀rọ̀ ajé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò gbèrú sí.

Ààrẹ fún ẹgbẹ́ náà Francis Meshioye sọ wí pé kò lè ṣí ìlọsíwájú bi ẹgbẹ́ náà o ba ni irẹpọ̀

Ó  wa pé fún àtìlẹ́yìn ìjọba àti irẹpọ̀ láàrin Ẹgbẹ́ náà kí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú bá le wa nínú ẹgbẹ́ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button