Take a fresh look at your lifestyle.

Ìwé Ètò Ìṣúná Ọdún Tó Ń Bọ̀: Ìjíròrò Àwọn Aṣòfin Wọ́ Ìpele Kejì

0 230

Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà tí ń ṣé ìjíròrò ẹlẹẹkeji lórò èròngbà Ààrẹ látí ná ìyè owó N27.5 tiriliọnu fún ètò ìṣúná 2024 èyì ti Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣé àfihàn rẹ̀ ní ọjọ́ kọkandinlọgbọn Oṣù kọkànlá, fún ibuwọlu tí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin tí Orílẹ̀-èdè.

Ifọrọwọrọ bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn aṣòfin lẹyìn tí wọ́n ká ìwé ètò Ìṣúná tí Orílẹ̀-èdè náà ní igbà Kéjì ní ọjọ́ Ẹtì.

Àwọn aṣòfin nínú àríyànjiyàn wọ́n tí tún ń bèèrè fún alékun owó fún àwọn oún amayedẹrun, òpópó-ònà, ètò ẹ̀kọ́, iná, àtí iṣẹ́ ọ̀gbìn, láàrín àwọn mìíràn ní orílẹ̀-èdè náà.

Wọ́n tún pé fún àdínkù nínú ẹyà-wò wọ́n, kí wọ́n sì pese ìṣúná fún ètò ààbò àtí àlàáfíà ní àgbègbè Niger- Delta fún ìlọsíwájú iṣelọpọ èpò rọbi.

Ni Ọjọ́rú ní Ààrẹ Bola Tinubu ṣé agbekalẹ ìwé ètò Ìṣúná pẹ̀lú iye 27.5 tiriliọnu náírà fún ọdún 2024, ṣáájú ìpàdé àpapọ tí Ile-igbimọ Aṣòfin méjèèjì, o sí rọ̀ wọ́n látí yàrá sí àyẹwò ìwé ètò ìṣúná náà kò tòó tó Oṣù kínní Ọdún tó ń bọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button