Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ìfowópamọ́ Àpapọ̀ Ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Ti Pàṣẹ kíkójáde, Gbígbà Owó Àtijọ́ Àti Tuntun Fún Gbogbo Àwọn Ilé Ìfowópamọ́

0 102

Lójúnà àti tẹ̀lé ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Àpapọ̀ ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó wáyé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n osù kọkànlá níbi tí ilé ẹjọ́ ti gba ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ amòfin àgbà wọlé, èyí tí ó pè fún ìsúnsíwájú aláìní gbèdéke fún níná owó àtijọ́ àti tuntun, báńkì àpapọ̀ pàṣẹ fún gbogbo àwọn ilé ìfowópamọ́ tí ó wà jákè-jádò gbogbo Nàìjíríà láti tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́

 

Nínú ìfọ̀rọ̀léde èyí tí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ se, èyí tí adelé ọ̀gá àgbà fún ètò ìbánisọ̀rọ̀ fún àjọ náà fi ọwọ́ sí ni ó ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ilé ìfowópamọ́

 

Ó wá pàrọwà sí gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti tẹ̀síwájú níbi níná àti gbígba owó àtijọ́ àti tuntun.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button