Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò agbègbèTaraba: PDP gbégbá orókè ní gbogbo LGA mẹ́rìndín-lógún

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 72

Àwọn Olùdíje fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Taraba ti palẹ̀mọ́ gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìndín-lógún ìpínlẹ̀ náà tán nínú ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní ìpínlẹ̀ náà.

Alaga igbimọ olominira to n mojuto eto idibo ni ipinlẹ Taraba, SIEC, Oloye Philip Duwe ṣalaye yii ni ọjọ Aiku nigba ti o n kede esi ibo ọjọ Abamẹta, ni olu ile-iṣẹ igbimọ naa ni Jalingo.

Duwe sọ pe wọn kede esi ibo ipo Kansilọ marunle-lọgọjọ ni oriṣiriṣi ijọba agbegbe naaa.

Esi ibo ti wọn kede ni awọn ibudo ikabo ba ofin mu, eleyi ti a n ṣe bayii ni lati fidi ohun ti wọn ti kede mulẹ.

Adupẹ lọwọ awọn akọroyin fun alaye to gun rerge lati ibẹrẹ pẹpẹ irin ajo naa titi di asiko yii.

 “Bi asiko yii ṣe le to, ẹ tun ṣe afihan ifọkansi ati aikaarẹ ọkan. E sin orilẹ-ede baba yin tọkantọkan ti ẹ si fakọ yọ.

 “Bi wọn ṣe n gbegba oroke ninu ibo naa ni wọn n fidi rẹmi ninu rẹ.A wa rọ awọn ti ibo yii ko tẹ lọrun. A ni ojuṣe lati jẹ ki alaafia jọba bi a ti n gbadun alaafia tẹlẹ naa.

Ẹyin ti ẹ gbegba oroke, eyi le jẹ ọjọ to dara fun yin ṣugbọn ẹ rẹra yin silẹ, ki ẹ si dupe fun aṣeyọri naa.Fun eyin ti ẹ fidi rẹmi, o le jẹ igba ti ko rọrun ṣugbọn fun igba ie ni.E kun fun adura ki ẹ si foju si nnkan ti e n ṣẹ.,” Duwe sọ bayii.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.

button