Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ àwọn Ọmọ Ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Se Ìdàrò Ọ̀gagun Àgbà Chris Alli Tó Jáde Láyé.

0 44

Ọ̀gá àgbà pátápátá fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ológun ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Taoreed Lagbaja ti fí ẹdun ọkan rẹ hàn nípa ikú Ọ̀gagun Àgbà tó tí feyinti Mohammed Chris Alli èyí to jade láyé.

Nínú àtẹ̀jáde kàn láti ọwọ́ alukoro fún ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun Onyema Nwachukwu, o ní iku Ọ̀gagun Àgbà náà jẹ ohun iyalẹnu púpọ̀.

Ọ̀gagun Àgbà náà jade láyé ni ọjọ́ kankandinlogun oṣù kọkànlá ọdún 2023 ni ilé ìwòsan ti awọn ọmọ Ológun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ni kété tí Ìròyìn ìbànújẹ náà kàn Ọ̀gagun Àgbà Taoreed Lagbaja létí, ni o ti fi ẹdun ọkan rẹ  hàn sí àwọn ẹbí, ara, ọrẹ ojúlùmò àti gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ológun pátápátá.

Ó wá gbàdúrà  fún ẹbi wí pé kí Ọlọrun wa pẹ̀lú wọn.

Leave A Reply

Your email address will not be published.

button