Ààrẹ Ẹgbẹ́ àwọn Onímọ̀ nípa oyún, Dókítà Mariya-Mukhtar Yola, ti ṣàlàyé wí pé àwọn aláboyún míràn tí ilé ọmọ rẹ kò lágbára tó, àti èyí tí ẹnu ile ọmọ rẹ kò ti dáradára leè fa ki wọn bímọ láìpé ọjọ́.
Ó sọ èyí di mímọ̀ níbi ayajọ ọjọ́ àwọn ọmọ tí kò gbọ́,ati láti dá àwọn ènìyàn lẹkọ ohun ti o n fa,pẹ̀lú ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ.
Yola ni àwọn aláboyún gbọdọ̀ ma lo sí ilé ìwòsan fún àyẹwò ati ki wọn rí wí pé wọ́n Simi dáradára
Ó ní nípa ṣíṣe èyí yóò jẹ ki ìrànlọ́wọ́ wa fún aláboyún tí irú nkán yìí ba ṣẹlẹ sí, o ní yóò mú kí ọmọ náà pé nínú rẹ titi di ọjọ́ ìkúnlẹ̀.
Ó tún ṣàlàyé wí pé àwọn ọmọ kogbo Kogbo yìí ń kojú ọpọlọpọ ìdààmù ki wọn tó dàgbà, ni èyí tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sì gba ibe lọ.
Leave a Reply