Ààrẹ ìgbìmọ̀ Yúróópù, Ursula von der Leyen ti sọ pé òun kò lọ́wọ́ sí “ṣíṣí àwọn ọmọ Palestine nípò padà pẹ̀lú ipá” lásìkò ìpàdé kan ní Cairo pẹ̀lú ààrẹ Egypt, Abdel Fattah al-Sisi.
Von der Leyen wa dupẹ lọwọ Egypt fun ipa pataki to ko ninu pipese ati ṣiṣeto iranlọwọ fun awọn ọmọ Palestine ti o ni ipalara, ninu ifiranṣe rẹ ti o fi sori X, ti a mọ tẹlẹ sí Twitter.
Awọn adari mejeeji ṣe ijiroro lori “laasigbo iranlọwọ ti o n lọ lọwọlọwọ bayii, ni Gaza” ati agbeyẹwo “Aṣeyọri oṣelu to da lori atunṣe orilẹ-ede meji,” ti Israel si n ṣeto ipolongo ologun ni Gaza lẹyin ikọlu awọn Hamas ni ọjọ keje, oṣu kẹwaa.
Gẹgẹ bi ijọba Hamas ṣe sọ, o kere ju awọn ẹgbẹrun mejila eniyan, pẹlu awọn ẹgbẹrun marun ọmọde, ni wọn ti paganu ẹmi wọn ni Gaza, lati igba ti Israel ti bẹrẹ ikọlu ni agbegbe Palestine, losu to kọja.