Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbẹ̀mí ara ẹni: ìjọba Eko rọ àwọn ọkùnrin láti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn síta

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 70

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti rọ àwọn ọkùnrin láti pa Àṣà àti máa dákẹ́ dà kí wọ́n ó sì sọ̀rọ̀ síta, láti dáwọ́ èrò ìgbẹ̀mí ara ẹni dúró.

Ìyáàfin Titilọla Vivour-Adeniyi, Akọwe Alaṣẹ, ile-iṣẹ abẹle ati ibalopọ ipa ti ipinlẹ EkoLagos (DSVA), ni o pa aṣẹ yii ni Ikẹja, lasiko ayẹyẹ lati ṣami Ayajọ Ọkunrin Kariaye 2023 . Akọle Ayẹyẹ naa si ni ”Ki a maa faaye gba ki ọkunrin gbẹmi ara rẹ”.

Vivour-Adeniyi sọ pe, ni ọdọọdun, mẹta-le-ni-ẹẹdẹgbẹrin ẹgbẹrun eniyan ni o n gbẹmi ara rẹ, ti awọn to pọ si si n tun gbiyanju lati ṣe bẹẹ, ti o si jẹ ẹlẹekẹrin ọna iku to pọ ju laarin awọn ọmọ ọdun mẹẹdogun si ọdun mọkandin-lọgbọn kaakiri agbaye ni ọdun 2019.

Gẹgẹ bi o ti sọ, gbogbo iku igbẹmi araẹni ni o jẹ ibanujẹ fun ẹbi, ilu, ati orilẹ-ede lapapọ, pẹlu awọn eniyan ti ẹni bẹẹ fi silẹ.

Akọwe Alaṣẹ naa tun wa sọ pe bi iku igbẹmi araẹni ṣe jẹ eewọ ni Naijiria, bi o ṣe wa n pọ si jẹ nnkan ti o n kọni lominu, ti akọsilẹ si fihan pe awọn ọkunrin ni o pọju ninu wọn.

O wa sọ pe, idi niyi ti DSVA wa ṣami ọjọ Kariaye naa, lati gba awọn ọkunrin niyanju lati kọ awọn ọdọ-kunrin wọn ni iyi, iwa ati ojuṣe lati jẹ ọkunrin

Leave A Reply

Your email address will not be published.

button