Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Gbajúmọ̀ Eléré-ìje Tí Ṣetán Látí Kópa Nínú Ìdíje ‘Warri/Effurun Peace Marathon’

0 137

Àwọn eléré ìdárayá ọ̀nà jíjìn ní Nàìjíríà ti fẹ́ díje nínú ìdíje ‘Warri/Effurun Peace Marathon (WEPM) 2023’. Ó jú ẹgbẹ̀rún méjì àwọn eléré ìdárayá ní á ń retí fún ìdíje ọjọ́ karundinọgbọn, Oṣù kọkànlá, ọdún yìí.

Emmanuel Gyan, tó aṣáájú ní ọdún 2022, yóò kojú Ìpènijà lílé látí ọdọ Ismail Sadjo àti Stephen Dalyop, làkókò tí Deborah Pam tó ṣáájú àwọn Obìnrin, yóò kojú ifigagbaga ní kíkún pẹ̀lú Joy Abiye, Elizabeth Nuhu àtí Patience Dalyop.

Gyan àtí Pam jẹ́ olubori ìyàlẹ́nu ní ọdún tó kọjá, ṣùgbọ́n Sadjo ati Abiye tí sọ ìpinnu wọ́n láti gbẹsan pẹ̀lú gbígbà ife tí ọdún yìí.

Eré-ìje náà ní itẹwọgbà látí ọwọ́ àjọ Eléré-ìje tí Nàìjíríà ‘Athletic Federation of Nigeria AFN’ àti àtìlẹ́yìn ìjọba Ìpínlẹ̀ Delta.

Leave A Reply

Your email address will not be published.

button