ARD fún ìjọba Enugu ní ìparí ìpinnu ọjọ́ mẹ́rìnlá láti gba àwọn Dókítà si
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà Àdúgbò (ARD) ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Fáfítì ti Ìmọ̀ Sáyẹ́ńsì àti Ìmọ̀ Ẹ̀rọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwòsàn (ESUTH), ti fún ìjọba Enugu ní ìparí ìpinnu ọjọ́ mẹ́rìnlá láti gba àwọn Dókítà si iṣẹ síi,kí ó sì pèsè ààbò.
Eleyii wa ninu alaye kan ti wọn fi sita ni ọjọ Abamẹta, lẹyin ipade pajawiri gbogbogboo ti ile-ikẹkọọ iwosan ti ESUT , Parklane, ní Enugu, ti o waye ni ọjọẸti, ọjọm kẹtadin-logun, 2023.
Aarẹ ARD-ESUT, Dokita Chukwunonso Ofonere ati Akọwe gbogbogboo, Dokita Ikemefuna Nnamani ni wọn jọ buwọlu iwe adehun naa.
Alaye naa wa rọ awọn alakoso ile ẹkọ iwosan ESUTH ati ijọba ipinlẹ lati pe ipe pajawiri lori gbigba awọn Dokita siṣẹ ni ile-iwosan naa.
Gẹgẹ bi alaye naa ṣe sọ, EGM sọ pe o ti pe ọgọfa ọjọ loni bayii ti ijọba ti ṣe ipinnu gbigba awọn osiṣẹ eleto iwosan ati awọn Dokita adugbo fun ARD, ṣugbọn ti ko tii si ipolowo fun igbesẹ naa.
O wa sọ pe wọn sọ fun EGM pe awọn oluṣakoso ti gbe igbeṣẹ lati pese aabo fun awọn Dokita ati awọn oṣiṣẹ ilera ni ile-iwosan naa.