Take a fresh look at your lifestyle.

Amokachi, Yobo Ní Pé Ó Dájú Pé Eagles Yóò Peregedé Fún Ife Àgbáyé

0 159

Àwọn Balógun ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹlẹ rí, Daniel Amokachi àti Joseph Yobo ní ìgboyà pé ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù Super Eagle náà yóò pàdà peregede fún ìdíje ife ẹyẹ Àgbáyé 2026.

Ṣáájú ifẹsẹwọnsẹ wọ́n Kejì pẹ̀lú Zimbabwe ní òní ọjọ́ Àìkú ní Kigali, Rwanda, àwọn àgbábọ́ọ̀lù rí náà tó tí gbá ife ẹyẹ AFCON gẹ́gẹ́ bí àgbábọ́ọ̀lù ní ọdún 1994 àti 2013 ṣé àfihàn ìgboyà wọ́n lórí ẹgbẹ́ náà láti peregede fún ìdíje ife àgbáyé 2026 tí Orílẹ̀-èdè USA, Canada àti Mexico yóò gbàlejò rẹ̀.

Wọ́n tún fí kún pé ìkọ Jose Peseiro ní àgbàrá látí gbá ife AFCON kẹrin fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ẹ̀wẹ̀, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ṣáájú eré náà, akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Super Eagles, Jose Peseiro, sọ pé ẹgbẹ́ náà yóò padà bọ̀ sípò lẹyìn ijakulẹ wọ́n pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Lesotho.

Leave A Reply

Your email address will not be published.

button