Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà Ṣé Ìpinnu Látí Tèsíwájú Lójú Ọnà Látí Máa Wá Àlàáfíà Ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom

0 161

Ààrẹ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Nàìjíríà tó tún jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom tẹ́lẹ̀ rí, Godswill Akpabio, tí tún ṣọ́ ìpinnu rẹ̀ látí ṣiṣẹ́ fún àlàáfíà àti ìdàgbàsókè tí Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, lójúnà ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀.

Akpabio ṣé ìlérí náà làkókò tó n sọ̀rọ̀ níbí ìdúpẹ́ tó wáyé fún Mínísítà fún Ọrọ̀ Èpò (Gas), Hon. Ekpekpe Ekpo, ní ‘Our Lady of Mercy Chaplaincy ní ìjọba ìbílẹ̀ Abak ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.

Nígbà tó n sọ̀rọ̀ síwájú, Akpabio gbóríyìn fún Hon. Ekpo fún ìrántí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run lẹyìn tí wọ́n yàn sípò gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ọmọ ẹgbẹ́ tí Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ayeye Ìdúpẹ́ náà, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Oluṣọ-agutan Umo Eno kesi àwọn ènìyàn Akwa Ibom látí gbaruku tí àwọn ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ náà, tó wà nípò aláṣẹ, fún ànfààní ìpínlẹ̀ náà.

Nínú ọ̀rọ̀ iṣaaju rẹ̀, Mínísítà náà, Hon. Ekpo, ṣàfihàn pé bí Ààrẹ Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ṣé ròyìn òún fún Ààrẹ Bola Tinubu láti di Mínísítà náà jẹ́ òun tó yá òún lẹ́nu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button