Àwọn àgbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Zimbabwe tí gbá àmì ayò kọ̀ọ̀kan (1-1) pẹ̀lú ìkọ Super Eagles tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nínú ifẹsẹwọnsẹ wọ́n Kejì nínú ìdíje ife ẹyẹ àgbáyé tí ọdún 2026 ní pápá ìṣèré ṣèré Huye, Butare, Rwanda.
Ìrètí ìkọ àgbábọ́ọ̀lù Super Eagles ní láti bóri ìfẹsẹ́wọ́nsẹ́ Kejì lẹ́yìn ìfẹsẹ́wọ́nsẹ́ pẹ̀lú Lesotho ní pápá ìṣèré Godswill Akpabio nílùú Akwa-Ibom, ní Ọjọ́bọ̀ tó kọjá.
Kìí ṣé òun tí wọ́n lérò ní wọ́n bá bí àgbábọ́ọ̀lù Zimbabwe Musona ṣé gbá bọ́ọ̀lù wọlé ní iṣẹju kẹrindinlọgbọn, títí tí ìdá kínní fí lọ́.
Victor Osimhen àti Taiwo Awoniyi kó rí ipá kàn sá làkókò náà kí wọ́n tó fí Victor Boniface, Kelechi Iheanacho àtí Osayi Samuel, rọ́po fún Ola Aina, Onyeka àti Nathan Tella bí Iheanacho ṣé gbá ayò wọlé fún ìkọ Super Eagle ní iṣẹju aadọrin dín mẹta.