Take a fresh look at your lifestyle.

Èsì Ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano: Moni Ìgbàgbọ́ Pé Ilé Ẹjọ́ Tó Gajù Lọ Yóò Ṣe Ìdájọ́ Òdodo – Èèkàn Nínú Ẹgbẹ́ Òṣèlú NNPP

0 308

Ẹni tíì ṣe èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s Party (NNPP), Olufemi Ajadi Oguntoyinbo ti fi ọwọ́ sọ̀yà pé ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ (Supreme Court) yóò ṣe ìdájọ òdodo lórí Gomina Ìpínlẹ̀ Kano, Abba Yusuf.

Oguntoyinbo tó jẹ́ bàbá ìsàlẹ̀ fún ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn (Correspondents’ Chapel of Oyo NUJ) ni Ìpínlẹ̀ Ọyọ, ní Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà ló ti korò ojú si bí ilé ẹjọ́ Kò-tẹ́mi-lọ́rùn to jókòó ní ìlú Abuja ṣe dá ẹjọ́ Abba Yusuf nù gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano, nígbà tó fi ìdájọ́ náà wé ìfàsẹ́yìn ránpẹ́.

Nínú àlàyé rẹ̀, Ajadi sọ pé ìgbìmọ̀ ẹlẹni-mẹta, eléyìí tí Onídàájọ M. A Adumeh léwájú fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé orúkọ Yusuf kò sí nínú ìwé ìforúkọsílẹ ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP, to tọ́ka sí abàla ìwé òfin ètò ìdìbò tó fìdí èyí múlẹ̀ pé kò lẹtọ lati dije du ipò Gómìnà.

Látàrí èyí, ilé ẹjọ́ Kò-tẹ́mi-lọ́rùn kéde Nasir Gawuna ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC gẹ́gẹ́ bíi olúborí nínú ètò ìdìbò yan Gómìnà tó kọjá, ṣùgbọ́n Ajadi, ẹni tí òun náà díje du ipò Gómìnà ṣugbọn tó fìdí rẹmi labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ni Ìpínlẹ̀ Ogun nínú ètò ìdìbò gbogboògbò tí ọdún yìí sọ pẹ̀lú ìgboyà pé, ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga jùlọ yóò kéde Yusuf gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà.

Ajadi nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé inú òun kò bá dùn tí púpọ̀ nínú àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Kano bá lè dúró digbí láti ṣe àtìlẹ́yìn fún Abba Yusuf láti mú kí àfojúsùn ìṣèjọba ọdún mẹ́jọ ṣeéṣe, nígbà tó tẹnu mọ pé òun yóò ṣe àbẹ̀wò síi láti fún ni àtìlẹ́yìn tó yẹ.

Bákan náà ló tẹnu mọ́ọ pé ìgbésẹ tí ilé ẹjọ́ Kò-tẹ́mi-lọ́rùn gbé yìí kii ṣe ohun tó yẹ kí ilé ẹjọ́ dá sí, nítorí ọ̀rọ̀ láàrin ọmọ ẹgbẹ́ lasan ni.
O wá ké sí gbogbo èèyàn Ìpínlẹ̀ Kano lati lọ f’ọkàn balẹ̀ kí wọ́n sì máṣe ṣi iwá hú látàrí ohunkohun ti ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò bá ṣe.

Bẹẹ gẹ́gẹ́ ni Ajadi tún jẹ kó di mímọ̀ pé, iyalẹnu lo jẹ́ láti gbọ pé àwọn ilé ẹjọ́ méjèèjì takò ara wọn nínú idajọ́ wọn, ṣugbọn o rọ Abba Yusuf àti ẹni tíì ṣe Oludije du ipò Ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú náà, Aṣòfin Rabi’u Musa Kwakwanso láti f’ọkàn balẹ̀, kò sí gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú níyànjú láti fara balẹ̀ fún ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ tó gajù lọ.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.

button