Kòsí Ohun Èlò Ìtọ́jú Aláìsàn Ní Ilé Ìwòsàn Al-Shifa- Alákòóso Sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Ẹ̀dùn Ọkàn
Ilé Ìwòsàn Al-Shifa ti ìlú Gaza, èyí tí àwọn ọmọ Ogun Orílẹ̀-èdè Israel se ìkọlù sí ni ó ti se àfẹ́kù àwọn oun èlò ìtọ́jú aláìsàn, tí àwọn aláìsàn tí ó wà níbẹ̀ sì ń kérora látàrí àìsí àwọn ohun èlò náà
Muhammad Abu Salmiya sàpèjúwe ipò tí ilé ìwòsàn náà wà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó burú jọjọ tí ó sì nílò ìgbésẹ̀ ní kíákíá lójúnà àti dóòlà ẹ̀mí àwọn tí ó ń gba ìtọ́jú níbẹ̀
Ìròyìn fi yéwa pé àwọn Ọmọ Ogun Orílẹ̀-èdè Isreal sì wà ní gbọ̀ngàn ilé ìwòsàn náà tí wọ́n dìmọ́ra ogun, wọ́n sì ń yin ìbọn léra-léra, ti wọn sì ń ba àwọn ohun èlò ilé ìwòsàn náà jẹ́, èyí tí ó mú kí ìbẹ̀rù-bojo máa sẹlẹ̀ níbẹ̀.