Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Katsina Fọwọ́sowọ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Tí Ọ̀rọ̀ Kàn Láti Mú Ìgbòòrò Bá Ètò Ọ̀gbìn

0 83

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Katsina ti sàlàyé pé òun yóò fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àjọ àgbáyé tí o máa ń pèsè owó fún ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbìn láti se ìrànlọ́wọ́ fún àwọn àgbẹ̀ kí oúnjẹ le è sùwá bọ̀, tí yóò sì mú ìgbòòrò bá ètò ọrọ̀ ajé

 

Akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ náà, Alhaji Abdullahi Garba-Faskari ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà níbi ìpàdé kan tí ó wáyé pẹ̀lú àwọn asojú àjọ àgbáyé tí ó maá n pèsè owó fún ìdàgbàsókè ètò ọ̀gbìn.

 

Ó tẹ̀síwájú pé ìgbésẹ̀ náà yóò mú ìgbòòrò bá ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé. Ó wá fi àrídájú hàn pé Ijọba Ipinlẹ Katsina ti gbaradi lati se iranlọwọ fun eto naa.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button