Ìfiga-gbága Tí Ó Wáyé Láàrin Nàìjíríà Àti Lesotho, Iná Nàìjíríà Jó Àjórẹ̀yìn- Peseiro
Akọ́nimọ̀ọ́gbá Àjọ Agbábọ́ọ̀lù Super Eagles ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Jose Peseiro ti sàlàyé pé àbájáde ìfiga-gbága eré bọ́ọ̀lù láàrin Naijiria ati Lesotho tí ó parí sí jíjẹ àmì ayò kọ̀ọ̀kan láti ọwọ́ ikọ̀ méjéèjì níbi ìsíde fún ìkójú òsùwọ̀n eré ìdárayá FIFA ti ọdún 2026 ti àgbáyé, jẹ́ èyí tí kò so èso rere fún Super Eagles
Peseiro síṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà níbi àpérò tí ó wáyé lẹ́yìn ìfiga-gbága náà, èyí tí ó wáyé ní ìlú Uyo, ní Ọjọ́bọ̀
Ìròyìn fi yéwa pé àwọn olólùfẹ́ ikọ̀ Super Eagles fi àìdùnnú ọkàn hàn lórí àbájáde eré ìdárayá náà, wọ́n sì gbàwọ́n níyànjú lórí àwọn ìkópa tí yóò wáyé ní ọjọ́ ìwájú.
Leave a Reply