Akọ̀wé Àjọ Commonwealth, Hon Patricia Scotland KC ti késí adarí àwọn obìnrin láti siṣẹ́pọ̀ lójúnà àti fi òpin sí aáwọ̀ ìdílé àti ìwà ìfipá-báni-lòpọ̀
Ó pe ìpè náà níbi àpérò kan tí àjọ Commonwealth se, èyí tí ó wáyé ní ìlú London láti wá ìdáàbò bò fún àwọn obìnrin kúrò níbi ewu ìfipá-báni-lòpọ̀ ati fífi ìyà jẹ awọn Obinrin
̀Ijíròrò wáyé lórí àmójútó, ètò ati ìtọ́jú tí ó péye àti ọ̀nà àbáyọ lati fi òpin sí ìlòkulò àwọn obìnrin àti ìfipá-báni-lòpọ̀.