Òjò tó pọ̀ tó fá omí yalé fá ikú àwọn ènìyàn tí kó dín ní mọkanlelọgbọ̀n káàkiri àwọn àgbègbè Orílẹ̀-èdè Somalia, Ìjọba Somalia sọ.
Àwọn olùgbé àgbègbè Beledweyne àti àárín gbùngbùn Somalia, ní a tí ríi nínú ìdààmú omí yalé.
Ọkàn nínú àwọn olùgbé àgbègbè náà Ahmed Idow ṣàpèjúwe ipò tí àgbègbè náà wà bí òun tó burú púpọ̀, o sí fí kún pé “awọn ènìyàn n sá àsálà fún ẹmi wọ́n latari àgbàrá omí náà.
Láti Oṣù Kẹwàá, ní omí tí ń dá Orílẹ̀-èdè náà láàmú bó ṣé lé ènìyàn bí mílíọ̀nù kàn àbọ̀ kúrò ní ibùgbé wọ́n. Mínísítà fún Ìròyìn ló sọ èyí fún àwọn oníròyìn ní Àìkú, ní Mogadishu, Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè náà